Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

O kó àwọn Israẹli ènìyàn rẹ jáde láti Ejibiti pẹ̀lú iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá.

Jeremiah 32:21 in English

Jeremiah 32:21 · Berean Standard Bible

You brought Your people Israel out of the land of Egypt with signs and wonders, with a strong hand and an outstretched arm, and with great terror.

Context

19Títóbi ni ìgbìmọ̀, àti alágbára ní í ṣe, ojú rẹ̀ ṣì sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn; láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀. 20O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní Ejibiti. O sì ń ṣe é títí di òní ní Israẹli àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ. 21O kó àwọn Israẹli ènìyàn rẹ jáde láti Ejibiti pẹ̀lú iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá. 22Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. 23Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o pàṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.