Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síbẹ̀ a ó fi ìlú náà fún àwọn ará Babeli, ìwọ Olúwa Olódùmarè sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”

Jeremiah 32:25 in English

Jeremiah 32:25 · Berean Standard Bible

Yet You, O Lord GOD, have said to me, ‘Buy for yourself the field with silver and call in witnesses, even though the city has been delivered into the hands of the Chaldeans!’”

Context

23Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o pàṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn. 24“Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe kórajọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kaldea tí ń gbóguntì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i. 25Síbẹ̀ a ó fi ìlú náà fún àwọn ará Babeli, ìwọ Olúwa Olódùmarè sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ” 26Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá pé: 27“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara. Ǹjẹ́ ohun kan ha a ṣòro fún mi bí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.