Jeremiah 31:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,” ni Olúwa wí. “Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.
Jeremiah 31:17 in English
Jeremiah 31:17 · Berean Standard Bible
So there is hope for your future, declares the LORD, and your children will return to their own land.
Context
15Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“A gbọ́ ohùn kan ní Rama
tí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.
Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀;
kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,
nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.” 16Báyìí ni Olúwa wí:
“Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún
àti ojú rẹ nínú omijé;
nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,”
ni Olúwa wí.
“Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá. 17Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,”
ni Olúwa wí.
“Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn. 18“Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé,
‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́
èmi sì ti gbọ́ ìbáwí.
Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà,
nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi. 19Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà,
mo ronúpìwàdà,
lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀,
èmi lu àyà mi.
Ojú tì mí, mo sì dààmú;
nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.