Jeremiah 3:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀, ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ” ni Olúwa wí.
Jeremiah 3:13 in English
Jeremiah 3:13 · Berean Standard Bible
Only acknowledge your guilt, that you have rebelled against the LORD your God. You have scattered your favors to foreign gods under every green tree and have not obeyed My voice,’” declares the LORD.
Context
11Olúwa wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ. 12Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:
“ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí.
‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́,
nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí.
Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé. 13Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,
ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì
lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀,
ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ”
ni Olúwa wí. 14“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni. 15Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.