Jeremiah 3:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ.
Jeremiah 3:11 in English
Jeremiah 3:11 · Berean Standard Bible
And the LORD said to me, “Faithless Israel has shown herself more righteous than unfaithful Judah.
Context
9Nítorí ìwà èérí Israẹli kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi. 10Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Juda arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olóòtítọ́,” ni Olúwa wí. 11Olúwa wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ. 12Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:
“ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí.
‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́,
nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí.
Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé. 13Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,
ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì
lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀,
ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.