Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

Jeremiah 29:20 in English

Jeremiah 29:20 · Berean Standard Bible

So hear the word of the LORD, all you exiles I have sent away from Jerusalem to Babylon.

Context

18Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn, Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí. 19Nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ní ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí. 20Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 21Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Kolaiah àti nípa Sedekiah ọmọ Maaseiah tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an. 22Nítorí tiwọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Babeli láti Juda: ‘Olúwa yóò ṣe yín bí i Sedekiah àti Ahabu tí ọba Babeli dáná sun.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.