Jeremiah 29:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí tiwọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Babeli láti Juda: ‘Olúwa yóò ṣe yín bí i Sedekiah àti Ahabu tí ọba Babeli dáná sun.’
Jeremiah 29:22 in English
Jeremiah 29:22 · Berean Standard Bible
Because of them, all the exiles of Judah who are in Babylon will use this curse: ‘May the LORD make you like Zedekiah and Ahab, whom the king of Babylon roasted in the fire!’
Context
20Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 21Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Kolaiah àti nípa Sedekiah ọmọ Maaseiah tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an. 22Nítorí tiwọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Babeli láti Juda: ‘Olúwa yóò ṣe yín bí i Sedekiah àti Ahabu tí ọba Babeli dáná sun.’ 23Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Israẹli, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí Èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni Olúwa wí. 24Wí fún Ṣemaiah tí í ṣe Nehalami pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.