Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn, Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí.

Jeremiah 29:18 in English

Jeremiah 29:18 · Berean Standard Bible

I will pursue them with sword and famine and plague. I will make them a horror to all the kingdoms of the earth—a curse, a desolation, and an object of scorn and reproach among all the nations to which I banish them.

Context

16Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi àti ní ti gbogbo ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú yìí; àní ní ti àwọn ènìyàn yín tí kò bá yín lọ sí ìgbèkùn, 17bẹ́ẹ̀ ni, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín wọn; Èmi yóò ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ. 18Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn, Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí. 19Nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ní ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí. 20Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.