Jeremiah 23:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí síbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn. Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀.
Jeremiah 23:21 in English
Jeremiah 23:21 · Berean Standard Bible
I did not send these prophets, yet they have run with their message; I did not speak to them, yet they have prophesied.
Context
19Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde
pẹ̀lú ìbínú à fẹ́ yíká ìjì yóò fẹ́ sí
orí àwọn olùṣe búburú. 20Ìbínú Olúwa kì yóò yẹ̀
títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ,
ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké. 21Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí
síbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn.
Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀,
síbẹ̀ wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀. 22Ṣùgbọ́n ì bà ṣe pé wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi,
wọn ìbá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi.
Wọn ìbá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi fun àwọn ènìyàn
wọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nà
àti ìṣe búburú wọn. 23“Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?”
ni Olúwa wí,
“kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jíjìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.