Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ.

Jeremiah 2:33 in English

Jeremiah 2:33 · Berean Standard Bible

How skillfully you pursue love! Even the most immoral of women could learn from your ways.

Context

31“Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ Olúwa: “Mo ha ti di aginjù sí Israẹli tàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri? Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri; àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’ 32Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye. 33Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ. 34Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀ àwọn tálákà aláìṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́ níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé. Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí 35ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀; kò sì bínú sí mi.’ Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.