Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.

Jeremiah 19:8 in English

Jeremiah 19:8 · Berean Standard Bible

I will make this city a desolation and an object of scorn.* All who pass by will be appalled and will scoff at all her wounds.

Context

6Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa. 7“ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀. 8Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀. 9Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’ 10“Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.