Jeremiah 19:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’
Jeremiah 19:9 in English
Jeremiah 19:9 · Berean Standard Bible
I will make them eat the flesh of their sons and daughters, and they will eat one another’s flesh in the siege and distress inflicted on them by their enemies who seek their lives.’
Context
7“ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀. 8Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀. 9Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’ 10“Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ. 11Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.