Jeremiah 18:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan.
Jeremiah 18:9 in English
Jeremiah 18:9 · Berean Standard Bible
And if at another time I announce that I will build up and establish a nation or kingdom,
Context
7Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun, 8tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. 9Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn. 11“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.