Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi.

Jeremiah 18:22 in English

Jeremiah 18:22 · Berean Standard Bible

Let a cry be heard from their houses when You suddenly bring raiders against them, for they have dug a pit to capture me and have hidden snares for my feet.

Context

20Ṣe kí a fi rere san búburú? Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi. Rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 21Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn lójú ogun. 22Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi. 23Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ gbogbo ète wọn láti pa mí, má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ. Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.