Jeremiah 18:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣe kí a fi rere san búburú? Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi. Rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Jeremiah 18:20 in English
Jeremiah 18:20 · Berean Standard Bible
Should good be repaid with evil? Yet they have dug a pit for me. Remember how I stood before You to speak good on their behalf, to turn Your wrath from them.
Context
18Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.” 19Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa,
gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ. 20Ṣe kí a fi rere san búburú?
Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi.
Rántí pé mo dúró níwájú rẹ,
mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn,
láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 21Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn
jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà
jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó
jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn
kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
wọn lójú ogun. 22Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn
nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun
kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́
kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.