Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí; tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára, ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn.

Jeremiah 15:19 in English

Jeremiah 15:19 · Berean Standard Bible

Therefore this is what the LORD says: “If you return, I will restore you; you will stand in My presence. And if you speak words that are noble instead of worthless, you will be My spokesman. It is they who must turn to you, but you must not turn to them.

Context

17Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn, n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀; mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi. 18Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun? 19Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí; tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára, ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn. 20Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára, sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí; wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ, nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni Olúwa wí. 21“Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.