Jeremiah 15:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára, sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí; wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ, nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 15:20 in English
Jeremiah 15:20 · Berean Standard Bible
Then I will make you a wall to this people, a fortified wall of bronze; they will fight against you but will not overcome you, for I am with you to save and deliver you, declares the LORD.
Context
18Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,
tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?
Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,
gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun? 19Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí,
“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá
kí o lè máa sìn mí;
tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára,
ìwọ yóò di agbẹnusọ mi.
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;
ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn. 20Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára,
sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí;
wọn ó bá ọ jà
ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ,
nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ
láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,”
ni Olúwa wí. 21“Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn,
Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.