Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn, jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn; nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

Jeremiah 11:20 in English

Jeremiah 11:20 · Berean Standard Bible

O LORD of Hosts, who judges righteously, who examines the heart * and mind, let me see Your vengeance upon them, for to You I have committed my cause.

Context

18Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí. 19Mo ti dàbí ọ̀dọ́-àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; n kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé: “Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀; jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè, kí a má lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.” 20Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn, jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn; nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. 21“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Anatoti tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa.’ 22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fì ìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.