Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fì ìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

Jeremiah 11:22 in English

Jeremiah 11:22 · Berean Standard Bible

So this is what the LORD of Hosts says: “I will punish them. Their young men will die by the sword, their sons and daughters by famine.

Context

20Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn, jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn; nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. 21“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Anatoti tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa.’ 22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fì ìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. 23Kò ní ṣẹ́kù ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Anatoti ní ọdún ìbẹ̀wò wọn.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.