Jeremiah 10:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn, wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.
Jeremiah 10:3 in English
Jeremiah 10:3 · Berean Standard Bible
For the customs of the peoples are worthless; they cut down a tree from the forest; it is shaped with a chisel by the hands of a craftsman.
Context
1Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli. 2Báyìí ni Olúwa wí:
“Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí,
kí àmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín,
nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè. 3Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn,
wọ́n gé igi láti inú igbó,
oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀. 4Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.
Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣó
kí ó má ba à ṣubú. 5Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko,
òrìṣà wọn kò le è fọhùn.
Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé
wọn nítorí pé wọn kò lè rìn.
Má ṣe bẹ̀rù wọn;
wọn kò le è ṣe ibi kankan
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.