Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀.

Jeremiah 10:23 in English

Jeremiah 10:23 · Berean Standard Bible

I know, O LORD, that a man’s way is not his own; no one who walks directs his own steps.

Context

21Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè, wọn kò sì wá Olúwa: nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká. 22Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀, àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá! Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro, àti ihò ọ̀wàwà. 23Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀. 24Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ, kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo. 25Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́n, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.