Jeremiah 10:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀, àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá! Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro, àti ihò ọ̀wàwà.
Jeremiah 10:22 in English
Jeremiah 10:22 · Berean Standard Bible
Listen! The sound of a report is coming— a great commotion from the land to the north. The cities of Judah will be made a desolation, a haunt for jackals.*
Context
20Àgọ́ mi bàjẹ́,
gbogbo okùn rẹ̀ sì já.
Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́,
kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́,
tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi. 21Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè,
wọn kò sì wá Olúwa:
nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere
àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká. 22Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀,
àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá!
Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro,
àti ihò ọ̀wàwà. 23Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀,
kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀. 24Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan
kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ,
kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.