Jeremiah 10:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
Jeremiah 10:12 in English
Jeremiah 10:12 · Berean Standard Bible
The LORD made the earth by His power; He established the world by His wisdom and stretched out the heavens by His understanding.
Context
10Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,
òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé.
Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;
orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀. 11“Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ” 12Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,
ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,
ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀. 13Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo;
ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé.
Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,
ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀. 14Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀,
ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀,
nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni,
kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.