Jeremiah 1:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn.
Jeremiah 1:17 in English
Jeremiah 1:17 · Berean Standard Bible
Get yourself ready.* Stand up and tell them everything that I command you. Do not be intimidated by them, or I will terrify you before them.
Context
15Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.
“Àwọn ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró
ní ojú ọ̀nà àbáwọlé Jerusalẹmu.
Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn
àti sí gbogbo àwọn ìlú Juda. 16Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi
nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,
nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn
àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. 17“Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.