Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.”

Jeremiah 1:12 in English

Jeremiah 1:12 · Berean Standard Bible

“You have observed correctly,” said the LORD, “for I am watching * over My word to accomplish it.”

Context

10Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn. 11Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?” Mo sì dáhùn wí pé, “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.” 12Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.” 13Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá. 14Olúwa sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.