Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà.

Jeremiah 1:14 in English

Jeremiah 1:14 · Berean Standard Bible

Then the LORD said to me, “Disaster from the north will be poured out on all who live in the land.

Context

12Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.” 13Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá. 14Olúwa sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí. “Àwọn ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn ìlú Juda. 16Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀, nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.