Native Bible

Judges 8:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣekemu, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Abimeleki.

Judges 8:31 in English

Judges 8:31 · Berean Standard Bible

His concubine, who dwelt in Shechem, also bore him a son, and he named him Abimelech.

Context

29Jerubbaali ọmọ Joaṣi padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀. 30Àádọ́rin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó. 31Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣekemu, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Abimeleki. 32Gideoni ọmọ Joaṣi kú ní ògbólógbòó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ofira ti àwọn ará Abieseri. 33Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gideoni ni àwọn ará Israẹli ṣe àgbèrè tọ Baali lẹ́yìn, wọ́n fi Baali-Beriti ṣe òrìṣà wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.