Native Bible

Judges 8:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àádọ́rin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó.

Judges 8:30 in English

Judges 8:30 · Berean Standard Bible

Gideon had seventy sons of his own,* since he had many wives.

Context

28Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Midiani ba níwájú àwọn ọmọ Israẹli bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbé orí mọ́. Ní ọjọ́ Gideoni, Israẹli wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún. 29Jerubbaali ọmọ Joaṣi padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀. 30Àádọ́rin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó. 31Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣekemu, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Abimeleki. 32Gideoni ọmọ Joaṣi kú ní ògbólógbòó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ofira ti àwọn ará Abieseri.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.