Onidajọ 7:8
Judges 7:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà.
Judges 7:8 in English
Judges 7:8 · Berean Standard Bible
So Gideon sent the rest of the Israelites to their tents but kept the three hundred men, who took charge of the provisions and rams’ horns of the others. And the camp of Midian lay below him in the valley.
Context
6Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi. 7Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Midiani lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.” 8Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà.
Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà. 9Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́. 10Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Pura ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.