Native Bible

Judges 7:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi.

Judges 7:6 in English

Judges 7:6 · Berean Standard Bible

And the number of those who lapped the water with their hands to their mouths was three hundred men; all the others knelt to drink.

Context

4Olúwa sì tún sọ fún Gideoni pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.” 5Gideoni sì kó àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibi ìsun omi. Níbẹ̀ ni Olúwa ti wí fún un pé, “Kí ó pín àwọn ènìyàn náà sí ọ̀nà méjì. Ya àwọn tí ó fi ahọ́n wọn lá omi bí ajá kúrò lára àwọn tí ó kúnlẹ̀ láti mu omi pẹ̀lú ọwọ́ wọn.” 6Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi. 7Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Midiani lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.” 8Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.