Native Bible

Judges 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì tún sọ fún Gideoni pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.”

Judges 7:4 in English

Judges 7:4 · Berean Standard Bible

Then the LORD said to Gideon, “There are still too many people. Take them down to the water, and I will sift them for you there. If I say to you, ‘This one shall go with you,’ he shall go. But if I say, ‘This one shall not go with you,’ he shall not go.”

Context

2Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọmọ-ogun tí o kójọ sọ́dọ̀ ti pọ̀jù fún mi láti fi àwọn ogun Midiani lé wọn lọ́wọ́, kí Israẹli má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là, 3sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsin yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gileadi.’ ” Báyìí ni Gideoni ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sì dúró. 4Olúwa sì tún sọ fún Gideoni pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.” 5Gideoni sì kó àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibi ìsun omi. Níbẹ̀ ni Olúwa ti wí fún un pé, “Kí ó pín àwọn ènìyàn náà sí ọ̀nà méjì. Ya àwọn tí ó fi ahọ́n wọn lá omi bí ajá kúrò lára àwọn tí ó kúnlẹ̀ láti mu omi pẹ̀lú ọwọ́ wọn.” 6Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.