Onidajọ 7:2
Judges 7:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọmọ-ogun tí o kójọ sọ́dọ̀ ti pọ̀jù fún mi láti fi àwọn ogun Midiani lé wọn lọ́wọ́, kí Israẹli má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là,
Judges 7:2 in English
Judges 7:2 · Berean Standard Bible
Then the LORD said to Gideon, “You have too many people for Me to deliver Midian into their hands, lest Israel glorify themselves over Me, saying, ‘My own hand has saved me.’
Context
1Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jerubbaali (èyí ni Gideoni) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bàá a orísun Harodi. Àwọn ogun Midiani sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè More. 2Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọmọ-ogun tí o kójọ sọ́dọ̀ ti pọ̀jù fún mi láti fi àwọn ogun Midiani lé wọn lọ́wọ́, kí Israẹli má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là, 3sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsin yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gileadi.’ ” Báyìí ni Gideoni ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sì dúró. 4Olúwa sì tún sọ fún Gideoni pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.