Native Bible

Judges 7:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jerubbaali (èyí ni Gideoni) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bàá a orísun Harodi. Àwọn ogun Midiani sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè More.

Judges 7:1 in English

Judges 7:1 · Berean Standard Bible

Early in the morning Jerubbaal * (that is, Gideon) and all the men with him camped beside the spring of Harod. And the camp of Midian was north of them in the valley near the hill of Moreh.

Context

1Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jerubbaali (èyí ni Gideoni) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bàá a orísun Harodi. Àwọn ogun Midiani sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè More. 2Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọmọ-ogun tí o kójọ sọ́dọ̀ ti pọ̀jù fún mi láti fi àwọn ogun Midiani lé wọn lọ́wọ́, kí Israẹli má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là, 3sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsin yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gileadi.’ ” Báyìí ni Gideoni ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sì dúró.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.