Native Bible

Judges 7:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́.

Judges 7:9 in English

Judges 7:9 · Berean Standard Bible

That night the LORD said to Gideon, “Get up and go down against the camp, for I have delivered it into your hand.

Context

7Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Midiani lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.” 8Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà. 9Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́. 10Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Pura ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́ 11kí o sì fi ara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà. Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà.” Báyìí ni òun àti Pura ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu-ọ̀nà ibùdó yìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.