Native Bible

Judges 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Gideoni gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Israẹli ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Olúwa yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Midiani.”

Judges 7:15 in English

Judges 7:15 · Berean Standard Bible

When Gideon heard the dream and its interpretation, he bowed in worship. He returned to the camp of Israel and said, “Get up, for the LORD has delivered the camp of Midian into your hand.”

Context

13Gideoni dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi barle ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Midiani, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá dé bi wí pé àgọ́ náà dojúdé, ó sì ṣubú.” 14Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gideoni ọmọ Joaṣi ará Israẹli lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Midiani àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.” 15Nígbà tí Gideoni gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Israẹli ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Olúwa yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Midiani.” 16Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà. 17Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí mo bá dé igun ibùdó wọn ẹ ṣe ohun tí mo bá ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.