Onidajọ 7:13
Judges 7:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gideoni dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi barle ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Midiani, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá dé bi wí pé àgọ́ náà dojúdé, ó sì ṣubú.”
Judges 7:13 in English
Judges 7:13 · Berean Standard Bible
And as Gideon arrived, a man was telling his friend about a dream. “Behold, I had a dream,” he said, “and I saw a loaf of barley bread come tumbling into the Midianite camp. It struck the tent so hard that the tent overturned and collapsed.”
Context
11kí o sì fi ara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà. Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà.” Báyìí ni òun àti Pura ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu-ọ̀nà ibùdó yìí. 12Àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti gbogbo ènìyàn ìlà-oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí eṣú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ìbákasẹ wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú Òkun. 13Gideoni dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi barle ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Midiani, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá dé bi wí pé àgọ́ náà dojúdé, ó sì ṣubú.” 14Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gideoni ọmọ Joaṣi ará Israẹli lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Midiani àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.” 15Nígbà tí Gideoni gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Israẹli ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Olúwa yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Midiani.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.