Onidajọ 5:31
Judges 5:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn, nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.” Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.
Judges 5:31 in English
Judges 5:31 · Berean Standard Bible
So may all your enemies perish, O LORD! But may those who love You shine like the sun at its brightest.” And the land had rest for forty years.
Context
29Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;
àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé, 30‘Wọn kò ha ń wa kiri, wọn kò ha ti pín ìkógun bi:
ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,
fún Sisera ìkógun aṣọ aláràbarà,
ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,
àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,
gbogbo èyí tí a kó ní ogun?’ 31“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa!
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn,
nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”
Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.