Onidajọ 21:3
Judges 21:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sọkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Israẹli? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Israẹli lónìí?”
Judges 21:3 in English
Judges 21:3 · Berean Standard Bible
“Why, O LORD God of Israel,” they cried out, “has this happened in Israel? Today in Israel one tribe is missing!”
Context
1Àwọn ọkùnrin Israẹli ti búra ní Mispa pé, “Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Benjamini ní ìyàwó.” 2Àwọn ènìyàn náà lọ sí Beteli: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún kíkorò. 3Wọ́n sọkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Israẹli? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Israẹli lónìí?” 4Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà. 5Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti péjọ síwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mispa pípa ni àwọn yóò pa á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.