Native Bible

Judges 21:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọkùnrin Israẹli ti búra ní Mispa pé, “Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Benjamini ní ìyàwó.”

Judges 21:1 in English

Judges 21:1 · Berean Standard Bible

Now the men of Israel had sworn an oath at Mizpah, saying, “Not one of us will give his daughter in marriage to a Benjamite.”

Context

1Àwọn ọkùnrin Israẹli ti búra ní Mispa pé, “Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Benjamini ní ìyàwó.” 2Àwọn ènìyàn náà lọ sí Beteli: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún kíkorò. 3Wọ́n sọkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Israẹli? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Israẹli lónìí?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.