Native Bible

Judges 21:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà.

Judges 21:4 in English

Judges 21:4 · Berean Standard Bible

The next day the people got up early, built an altar there, and presented burnt offerings and peace offerings.

Context

2Àwọn ènìyàn náà lọ sí Beteli: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún kíkorò. 3Wọ́n sọkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Israẹli? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Israẹli lónìí?” 4Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà. 5Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti péjọ síwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mispa pípa ni àwọn yóò pa á. 6Àwọn ọmọ Israẹli sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Benjamini. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Israẹli lónìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.