Onidajọ 2:12
Judges 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú,
Judges 2:12 in English
Judges 2:12 · Berean Standard Bible
Thus they forsook the LORD, the God of their fathers, who had brought them out of the land of Egypt, and they followed after various gods of the peoples around them. They bowed down to them and provoked the LORD to anger,
Context
10Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Israẹli. 11Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali. 12Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú, 13nítorí tí wọ́n kọ̀ Olúwa sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti. 14Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.