Native Bible

Judges 17:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.

Judges 17:11 in English

Judges 17:11 · Berean Standard Bible

and agreed to stay with him, and the young man became like a son to Micah.

Context

9Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.” 10Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.” 11Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 12Nígbà náà ni Mika ya ará Lefi náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀. 13Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.