Onidajọ 17:9
Judges 17:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.”
Judges 17:9 in English
Judges 17:9 · Berean Standard Bible
“Where are you from?” Micah asked him. “I am a Levite from Bethlehem in Judah,” he replied, “and I am on my way to settle wherever I can find a place.”
Context
7Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda wá, tí í ṣe ìdílé Juda, ẹni tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, òun sì ṣe àtìpó níbẹ̀, 8ọkùnrin náà sì ti ìlú Bẹtilẹhẹmu ti Juda lọ, láti ṣe àtìpó ní ibikíbi tí ó bá rí. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Mika nínú àwọn ilẹ̀ òkè Efraimu. 9Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?”
Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.” 10Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.” 11Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.