Onidajọ 16:19
Judges 16:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun sì mú kí Samsoni sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀. Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
Judges 16:19 in English
Judges 16:19 · Berean Standard Bible
And having lulled him to sleep on her lap, she called a man to shave off the seven braids of his head. In this way she began to subdue him,* and his strength left him.
Context
17Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.” 18Nígbà tí Dẹlila rí i pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹlila ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Filistini pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Filistini padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́. 19Òun sì mú kí Samsoni sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀. Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ. 20Òun pè é wí pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.”
Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìnwá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira.” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀. 21Nígbà náà ni àwọn Filistini mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú un lọ sí Gasa. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.