Native Bible

Judges 12:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”

Judges 12:1 in English

Judges 12:1 · Berean Standard Bible

Then the men of Ephraim assembled and crossed the Jordan to Zaphon. They said to Jephthah, “Why have you crossed over to fight the Ammonites without calling us to go with you? We will burn your house down with you inside!”

Context

1Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.” 2Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn. 3Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.