Onidajọ 12:2
Judges 12:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn.
Judges 12:2 in English
Judges 12:2 · Berean Standard Bible
But Jephthah replied, “My people and I had a serious conflict with the Ammonites, and when I called, you did not save me out of their hands.
Context
1Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.” 2Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn. 3Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?” 4Nígbà náà ni Jefta kó gbogbo ọkùnrin Gileadi jọ, ó sì bá Efraimu jà. Àwọn ọkùnrin Gileadi sì kọlù Efraimu, nítorí wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gileadi jẹ́ àsáwọ̀ àwọn ará Efraimu àti ti Manase.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.