Native Bible

James 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín.

James 5:6 in English

James 5:6 · Berean Standard Bible

You have condemned and murdered the righteous, who did not resist you.

Context

4Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 5Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa. 6Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín. 7Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. 8Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀, nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.