Jakọbu 5:7
James 5:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò.
James 5:7 in English
James 5:7 · Berean Standard Bible
Be patient, then, brothers, until the Lord’s coming. See how the farmer awaits the precious fruit of the soil—how patient he is for the fall and spring rains.*
Context
5Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa. 6Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín. 7Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. 8Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀, nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. 9Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.