Jakọbu 3:2
James 3:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu.
James 3:2 in English
James 3:2 · Berean Standard Bible
We all stumble in many ways. If anyone is never at fault in what he says, he is a perfect man, able to control his whole body.
Context
1Ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí púpọ̀ nínú yín jẹ́ olùkọ́, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé àwa ni yóò jẹ̀bi jù. 2Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu. 3Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. 4Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.