Native Bible

James 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀.

James 3:4 in English

James 3:4 · Berean Standard Bible

Consider ships as well. Although they are so large and are driven by strong winds, they are steered by a very small rudder wherever the pilot is inclined.

Context

2Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu. 3Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. 4Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀. 5Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! 6Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.